Home iroyin Afunrasí ibà Lassa lé lọ́gọ́rùn-ún L’Ógùn – Ipaye
iroyin - August 14, 2017

Afunrasí ibà Lassa lé lọ́gọ́rùn-ún L’Ógùn – Ipaye

Komisona fun eto ilera ni ipinle Ogun, Dokita Bababtunde Ipaye lo n ba awon oniroyin soro pe awon afunrasi iba Lassa ti pe merindinlaadofa (106) bayii niile iwosan ijoba to wa ni Ijaiye, Abeokuta.

O ni pelu bi o se ri naa, ki awon ara ilu ma se beru nitori pe gbogbo re si wa ni ikawo awon. O ni awon maa moju to won fun ojo mokanlelogun ki awon to le so pe won ti ko arun naa tabi won ko koo. O ni bi awon se n foju to won naa ni awon tun n foju to ile ti okoookan won ti jade. O ni nitori pe, ti awon ko ba se bee, o lewu gidi fun ipinle naa.

Ipaye ni merindinlaadota (46) lo ti wa lodo awon tele titi di ojo Jimo ki o to wa di pe ogoji (40) kun un laarin Jimo si Sonde. O ni gbogbo awon to n moju to won ni awon ti pin ero to n se ayewo loore-koore fun. O ni bi ara won ba se n gbona si ati ori fifo ti ko tete lo ni awon fi le koko mo bi won ti ko arun iba naa abi won ko tii koo.

Komisona yii ro awon ara ilu ki won jowo je ki imototo won po sii lasiko yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…