Home iroyin Ẹ̀fún àbéèdì, Aiyeloja gé nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀
iroyin - August 13, 2017

Ẹ̀fún àbéèdì, Aiyeloja gé nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀

Iyalaenu nla lo je fun awon olugbe Obanla ni ilu Akure, ipinle Ondo ni igba ti okunrin kan ti o ti maa le ni ogoji odun bere si ni bo sokoto loju gbogbo ero, ti o si n fi bileedi ge nnkan omokunrin re, O fere koko ge nnkan omokunrin yii tan ki o to bo sori awon koro meji to wa nibe. O fe maa yo won sile ni okookan, eje si bere si ni tu jade bi omi ero ni awon eniyan ba boo.

Bi awon kan se sare gbee lo ile iwosan ni awon kan gba ago olopaa lo nitori ko ma lo yiwo mo won lowo ni ile-iwosan. Won ni awon ko fe se oore daran.

Nigba ti ara okunrin naa, Oluwole Aiyeloja bale die ni won foro wa lenu wo ti o si salaye die pe, emi kan lo n ti oun pe ki oun fi awon koro abe oun dajo ki iku ma ba pa oun. O ni o ti to bi ojo meloo kan ti orisiirisii nnkan buruku bee ti maa n so si oun lokan, pe o si maa n muu ni dandan fun oun ni gbogbo igba.

Pelu gbogbo iwadii awon eniyan, ko si arun opolo kankan ninu isesi re sugbon o dabi aransi tabi eedi ni ohun to n baa ja.

Femi Joseph to je Alukoro awon olopaa ni ipinle Ondo naa jeri si oro Aiyeloja. O ni ko tii si esun kankan ti awon le fi gbee lo si ile ejo bayii nitori pe ara re lo se lese, ko si fe pa ara re. O ni eni naa si ti wa ni ile-iwosan awon olopaa nitori ati le moju to o.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…