Home iroyin Ìwọ́de lórí àìlera Buhari
iroyin - August 10, 2017

Ìwọ́de lórí àìlera Buhari

Ailera Aare Mohammadu Buhari ti n da opolopo ede aiyede sile ni ilu Abuja bayii. Ojo Aje ose yii ni awon kan ti won pe ara won ni “OURMUMUDONDO” kora jo lati maa se iwode olojoojumo. Awon olopaa tile dun ikooko mo won ni ojo keji sugbon ko tu irun kankan lara won.

Ni owuro oni ojo Bo ni awon miran naa tun kora won jo ni elegbe-jegbe ati ni ologba-jogba lati maa so pe, eyin Buhari ni awon wa. Won ni adura lasan ni gbogbo wa nilo ni orileede yii kii se iwode pe ki Aare wale tabi ki o kowe fi ise sile.

Awon ajo yii ni Aare Buhari tele ofin ko to lo nipa gbigbe isakoso ijoba le igbakeji re lowo, iyen Ojogbon Yemi Osinbajo. Won ni gbogbo nnkan si n lo bi o ti to ati bi o ti ye. Sugbon awon ajo ti won ni ki Buhari wale tabi kowe fi ise sile ni iro pata-pata gbaa ni a n pa fun ara wa ti a ba ni aaye Buhari ko yo sile. Won ni Buhari kan je ki gbogbo nnkan duro rigidi bi omi adagun pelu aisi nile re.

Eyi ni o n to n sele lowo-lowo bayii ni olu-ilu Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…