Home LÁGBO ÀRÍYÁ E má ṣe jẹ́ kójú mi fọ́ tán – Lanrewaju Adepoju
LÁGBO ÀRÍYÁ - August 10, 2017

E má ṣe jẹ́ kójú mi fọ́ tán – Lanrewaju Adepoju

Se yooba bo won ni oju ni imole ara,ati pe oju la fii pete ero.Hun! O je nnkan ibanuje gbaa pe bi Olorun se bu kun wa lorile yii to,sibe,opo nnkan ni o nuwa, latari ai lakasi, ati abi lafojusun to gunmo fojo iwaju. Bi bee ko,se o ye ki wahala to bayii lorun Oloye Olanrewaju Adepoju, eni ti o fi. Iji n ji aye e re sin orile yii, titi dasiko yii lai ro kiko oro jo,sugbon ti o wa di asiko to ye ki ilu gbaruku tii,ti awujo wa n yori boro boro.Bi ko ba ri be e,se ko jo be e.Agba pede-pede, Oba ewi yii,lo ni ipenija oju lati nnkan bii odun die seyin,ti o si ti gbiyanju ,debii pe apa ti kun un, latari pe owo apekanuko ja baba yii ni tanmo o.

Ninu eto o ori redio kan ti won fa baba naa ni teete wa,ni o ti tu pere-pere,pe won ko bi Oun ni afoju o,sadede loju naa bere,ti oun si ro pe nnkan kekere ni,sugbon awon kan ti won so pe awon n sise abe iwosan oju ni won gbiyanju lori oju naa,sugbon, ti ayewo pada fidi re mule pe,okun teere kan ti o so oju po fun irorun gaaara ( retina) ti ja  .Ni kukuru ede,baba naa so pe, awon akosemose ti gba oun nimoran pe,oke okun ni atunse to fokanbale ti le wa si oju naa,bi be e ko,bi yoo se wa niyen .Anjaanu akewi naa so pe,gbogbo ise opolo ti oun ni lokan, ni idaamu oju yii ti begi dina won.

Ogbontarigi akewi naa ni,apa kun oun ni o,tori pe, owo ti o to milionu meje naira (#7m ) ni awon dokita nilo, lati sise abe  oju naa ni orileede India. Baba naa ni inu oun yoo dun pupo,bi oun ba ri alaaanu  iranwo owo ki oro naa to yiwo .Se awon agba bo won ni ko si n to bagba ninu je bi ifa ti ko lebo ‘ti ko letutu. Idunu saa ni ounje agba.

Iroyin Owuro gba pe o ye ki omo yooba atata o le kopa ti o joju lori oro baba yii.O fe e ma si ojulowo omo yooba ti ko ti bu mu ninu omi ogbon ohun imo Oba ewi yii.Yoo buru jai ki a ma lakasi ara a wa lasiko isoro,sugbon ki a maa wa pokiki  irufe eni be e ati ise owo o re leyin ti o ba rare ti iku fi ran an  ni irinajo aloode. Yoruba ronu o.Teni n teni ,akisa n taatan.  N je  tolori telemu, otookulu, oba ati ijoye, gbogbo eleyinju aanu pata,Omo yooba atata yi  Lanrewaju Akanmu Adepoju,dowo yin,eleeru ko gbodo sungi o,ijafara lewu,eeyan ti ko si tii ku,ko i moruuku ti yoo pa a.E pe olootu fun iranwo lori oro baba yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…