Home LÁGBO ÀRÍYÁ Ayẹyẹ ogún ọdún fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Providence Heights
LÁGBO ÀRÍYÁ - August 10, 2017

Ayẹyẹ ogún ọdún fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Providence Heights

Ile-iwe girama to fi ikale si adugbo Fagba ni Agege se ayeye olodoodun ti ogun ni ojo kokandinlogbon, osu keje odun 2017 ni gbongon ile-iwe naa.

Pa Oduyemi ati iyawo won ni ti eniyan ba gesin ninu awon, eni naa ko ni ko ese ni ibi ti inu awon dun de fun aseyori awon omo naa bo se lo ni irorun. Baba ni “a ki sore ero ka yo” awon omo yii ni lati te siwaju ninu eko won bi o tile je pe lilo won n dun awon.

Olori awon akekoo lobinrin, Oluwatosin Bolaji ni o ka ese bibeli “Owe. Ori keta, ese kinni titi de ikejo (Proverbs 3:1-8) nigba ti olori akekoo lokunrin, Owoyemi Gbolaga naa ka Luuku, ese karun-un, ori kinni titi de ikeje (Luke 5:1-7)

Die lara awon akekoo to n jade lo to gbebun lojo naa ni – Adebowale Daniel eni to dara ju ninu imo sayensi(Science) ati isiro (Mathematics), Oluwatosin Bolaji lo gba ebun ti imo sosia sayensi (Social Science), Aworan yiya (Fine Arts) ni Ogbonnaya Elizabeth gba, Ede Oyinbo (English language) ja mo Ifedayo Oluwaferanmi lowo, eni to wuwa to dara ju lokunrin (Best behave boy) ninu won ni Bamgboye Opeyemi nigba ti Olonade Atinuke gba ti obinrin (Best behave girl), Oladuja Progress lo gba ti imo komputa.

Ogbeni Ogunkola Olanrewaju ni o se idupe nipa fifi emi imoore han si tonile ati alejo nipa adura, owo ati ebun ye awon si lojo naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…