Home Orisirisi Ó yẹ kí ọmọ Nàìjíríà máa gbósùbà fún EFCC – Ribadu
Orisirisi - August 9, 2017

Ó yẹ kí ọmọ Nàìjíríà máa gbósùbà fún EFCC – Ribadu

Nuhu Ribadu ni olori akoko ajo EFCC ni asiko isejoba Olusegun Obasanjo. Oun lo bere ajo naa,o ni oun si mo riri ise naa. O ni ise to lagbara ni ise ti o si je ise elege ni ise ajo naa. Ribadu n ba awon oniroyin soro yii ni igba ti awon oniroyin muu mole ni ilu Ilesa, ipinle Osun nibi ayeye kan to lo.

Ribadu ni ise ifi emi wewu ni ise ajo EFCC, o ni nipa idi eyi, o ye ki a maa bo won ni nitori pe awon eniyan buruku yii ti wole si wa lara lopo. Won ti fere gbon koto oba gbe. Gbogbo owo ti o ye ki emi ati eyin maa fi soro ni awon kan ko ti won si n naa bi o ti wu won.

O ni awon eniyan buruku yii lagbara, won ni ipo ni eyi to je ko lewu fun awon to n dari ajo naa. Ribadu ni ko ni nira lopo ti awa omo Naijiria ba mo riri ise naa ti a si kun won lowo lati gbogun ti awon asebi naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…