Home Orisirisi Ah, ọ̀rọ̀ olósèlú! Fayose, Fayemi àti Ojudu jọ jókòó papọ̀ sínú bàálù kan!
Orisirisi - August 9, 2017

Ah, ọ̀rọ̀ olósèlú! Fayose, Fayemi àti Ojudu jọ jókòó papọ̀ sínú bàálù kan!

Oro awon oloselu, nnkan nla ni. Eni to ba tori won maa ja ija ajaagbila, oluware ko ni nnkan se ni. Koda, afaimo ki won ma fi ori oluware fo agbon.

Idi ni pe bi e ba ri ti awon oloselu n soro ija ni ita gbangba, o ni ibi ti won ti n pade, ti won jo n rerin-in si ara won. Koda, o seese ki won jo maa se awon nnkan miiran papo.

Foto kan to sese jade ni gbigbona felifeli lo tun fi idi oro yii mule.

Ninu foto naa, a ri Gomina Ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose; Minisita fun Oro Ohun Alumooni, Dokita Kayode Fayemi; ati Olubadamoran Aare Buhari lori Oro Oselu, Ogbeni Babafemi Ojudu; nibi ti won ti jo jokoo fegbe-kegbe ninu baalu helicopter kan.

IROYIN OWURO ko tii mo eni to ni baalu naa laarin won, sugbon won jo gun un lo si ode ni, ti ode naa si je ibi adura oku iya Gomina Rauf Aregbesola ti Ipinle Osun.

Awon oloselu meteeta naa ni won jo n tahun sira won tele lori ijoba ipinle Ekiti, paapaa idibo gomina odun 2019.

E wa wo aye lode bayii. Awon omoleyin won maa n fe fi ori gba ori nigba ti Fayose ba ta si Fayemi, tabi ti Fayemi ba ta si Fayose.

Sugbon, lokan awon oloselu yii, won mo pe okan soso ni awon. O kan je pe oja kan naa ni won n na ni!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…