Ọmọge onífíìmù fún ìjẹ̀bú ní red card
Osere fiimu kan to sese n jade sita, Ifeoluwa Olawale, ti soro lori ajosepo to wa laarin oun ati Tayo Amokade, ti adape re n je Ijebu.
Ede agbegbe ti Ijebu ti Tayo maa n so ninu fiimu lo fa a ti won fi n pe e ni Ijebu.
Oun ni Ifeoluwa fi se ategun sinu ise fiimu, to si maa n je bii oludamoran fun obinrin yii.
Nitori pe won n wole, wode, opo eniyan lo n so pe won n fe ara won.
Sugbon ninu alaye ti Ifeoluwa sese se, o ni loooto ni Ijebu ti ran oun lowo daadaa, amo ko si oro loko-laya laarin awon.
Ifeoluwa ni Ijebu ko enu ife si oun ri, sugbon oun ko gba fun un, nitori pe oun mo pe o ti niyawo nile.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…