Home Orisirisi D’Banj so idi to fi se igbeyawo bonkele
Orisirisi - August 8, 2017

D’Banj so idi to fi se igbeyawo bonkele

 

Akorin hiphop ti a mo si D’Banj ya opo eniyan lenu laipe yii, nigba ti iroyin sadede jade pe iyawo re ti bimo.

Awada ni awon eniyan koko pe oro naa tori won ko mo pe o ti niyawo.

Asiko naa ni oun naa wa je ko mo fun araye pe o ti se igbeyawo alaipariwo pelu orebibrin re to n je Didi.

D’Banj ti wa se alaye idi to fi se bee.

O ni ki oun to fe arabinrin naa ni bonkele, opo eniyan lo ti ko ogun le oun laya lori pe asiko ti to fun oun lati fe iyawo.

O ni oun tun gba pe bi ariwo ba ti poju lori igbeyawo, o le di awuyewuye, ki wahala si tibe jade.

D’Banj ni idi niyi ti oun ko fi pariwo lori igbeyawo oun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…