Nàìjírià ló ń pèsè Ẹja-àrọ̀ jù nílẹ̀ Adúláwọ̀ – Audu Ogbeh
Orilẹ-ede Naijiria ti di orilẹ-ede to n pese ẹja-arọ ju nilẹ adulawọ nipasẹ eto ijọba to dena gbigbe ẹja wọle lati oke-okun.
Minisita fun ipinlẹ lori ọgbin ati idagbasoke ilu ni o sọ eyi ni Abuja. Minisita naa ti orukọ rẹ n jẹ Sẹnatọ Heineken Lokpobiri, o sọ eyi di mimọ ninu apero ifọrọjomitoro ọrọ nipa owo ẹja.
Gẹgẹ bi nnkan ti ọgbẹni Lokpobiri sọ, eto ijọba to dena gbigbe ẹja wọ orilẹ-ede Naijiiria eyi ti ijọba apapọ gbe kalẹ lo mu igbega ba ọsin ẹja-arọ. O sọ pe tẹlẹ, orilẹ-ede Naijiiria maa n gbe ẹja wọle lati oke-okun. Eyi to sọ wa di orilẹ-ede to n gbe ẹja wọle julọ amọ eyi ti orin ti yipada bayii.
Minisita naa gboriyin fun AnWFPT fun ipa wọn gẹgẹ bi ẹgbẹ to n ri si tita ẹja ni orilẹ-ede adulawọ. O ṣeleri lati ran awọn ẹgbẹ bii; CAFAN, AOFFEN ati gbogbo ẹgbẹ to ba n ri si pipese ẹja ni Naijiiria.
Ẹni to ṣoju African Union (AU), Simplice Nouala sọ pe ilẹ adulawọ ni ọpọlọpọ ohun ti a le fi sin ẹja eyi ti o le pese owo to ba se idagbasoke ilu.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…