Home iroyin Ìwọ́de lórí àìlera Buhari
iroyin - August 7, 2017

Ìwọ́de lórí àìlera Buhari

Yoruba bo “won ni eni to rajo ti ko tete de ti je ki araye o robi roo”. Eyi gele ni o n sele ni orileede yii bayii. Owuro oni ni awon egbe kan ti kii se ti ijoba tun bere iwode ni ilu Abuja. Won ni “ki Buhari maa bo wale bayii tabi ki o kowe fi ipo Aare sile”.

Gbogbo atotonu arabinrin Lauretta Onochie to je oluba-Aare-damoran lori ero ayelujara lo dabi igba ti “eniyan n yin agbado si eyin igba ni oju awon egbe yii”. Arabinrin yii ni ko ye ki awon kan maa ko ara won jo lati maa si awon omo Naijiria lona. O ni Buhari gba aaye lati lo toju ara re, o si se gbogbo eto to ye fun igbakeji re gege bi o se wa ninu iwe ofin ile wa.

Charles Oputa ti gbogbo aye mo si Chally Boy ati Ogbeni Deji Adeyanju ni won tako alaye Arabinrin Lauretta. Won ni iwe ofin Naijiria ni abala kerinlelogoje (144) naa salaye pe o ye ki omo Naijiria to dibo yan Aare mo iru aisan to n se Aare won ati igba to maa pada wa si Naijiria. Won ni Aare ti lo bayii lati ojo kejilelaadorun-un (92days) ti ko si eda Olorun kan to le so igba to maa pada.

Awon egbe yii ni a ko tile tii ri nnkankan, won ni iwode naa maa te siwaju ni ipinle Eko ati awon ipinle miran pelu awon orileede kan ni oke okun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…