Home iroyin Fọ́tò Arthur Nzeribe ń ràn bìi iná ọyẹ́
iroyin - August 7, 2017

Fọ́tò Arthur Nzeribe ń ràn bìi iná ọyẹ́

Iyalenu nla-nla lo kuku je fun awon ebi ati ololufe Oloye Francis Arthur Nzeribe bi foto re se n kaakiri ori ero ayelujara. Ko si eni to mo igba ti enikan ya foto naa ti o si bere si ju kaakiri aye pelu awon oro iregun. Baba yii ti pe omo odun mejidinlogorin (78years) bayii.

Omo bibi ilu Orlu ni ipinle Imo ni baba naa. Alagba yii se seneto Naijiria lasiko Babangida ati Abacha. Ti opo wa ko ba gbagbe, oun ni o n gba iwaju gba eyin lasiko Babangida nipa egbe “Association for Better Nigeria” ABN. O lowo si bi Babangida se da ibo ti itan so pe ohun lo dara ju ti ko ni mago-mago lati igba awase ni orileede yii nu. Ibo ti Moshood Abiola ti jawe olubori ni June 12, odun 1993.

Baba yii lami laaka ki o to di pe arun gbee de, ko si eni ti agba o ni kan, amo awon eniyan ni baba yii ko lo igba ti owo ati agbara wa lowo re daadaa. Isubu baba yii koko bere ni igba ti Aare ile igbimo asofin igba naa Anyim Pius Anyim ni odun 2002 fi esun owo milionu mejilelogun kiko je kan an, O tun kuna ibo seneto ni ilu re leyin igba naa.

Eko ni eleyii je fun eni to ba ni ekoo ko, ”igba ni omo n ni, enikan kii laye” ni Yoruba maaa n wi. Eyin ti aye wa lowo yin bayii, e see daadaa nitori oni ko, nitori ola ni..

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…