Home iroyin Àwọn agbébọnrìn pa ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ilé ìjọ́sìn
iroyin - August 7, 2017

Àwọn agbébọnrìn pa ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ilé ìjọ́sìn

Ni idaji oni ni awon adihamora agbebonrin ya wo ile ijosin St Philips Catholic  to wa ni Amakwa Ozubulu ti ijoba ibile Ekwusigo ni ipinle Anambra. Bi isin se n lo lowo ni won kan dede ri awon eniyan buruku yii ti won di awon ona meteeta to wo ile ijosin naa pelu ibon yiyin lera-lera.

Eniyan ti ko din ni meedogun ba isele naa lo ni igba ti awon dokita si n du emi awon mokanlelogun ni  Nnamdi Azikiwe University Teaching Hospital, Anambra.

Gomina Wiliie Obiano gan-an ti sare se abewo si ile-ijosin naa, gege bi iwadii awon olopaa ipinle naa, won ni awon alagbara meji lo n ja ti won si wa ara won de ile-ijosin. Won ni awon mejeeji ko ki n se olugbe Naijiria sugbon ti won wale lati oke okun ti won si tun bere ija naa.

Aare Buhari, Saraki, Dogara pelu Gomina ipinle Anambra lo fa oju ro si iwa buruku yii. Won si se ileri lati fi owo sinkun ofin mu awon asebi naa. Gomina ipinle naa ti seleri lati nawo posi awon to ku ati lati sanwo awon to wa ni ile-iwosan.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…