Home iroyin Òsèlú mi fara jọ ti Tinubu – Fayose
iroyin - August 6, 2017

Òsèlú mi fara jọ ti Tinubu – Fayose

Gomina ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose ni o n salaye yii fun awon oniroyin ni opin ose yii. O ni lasiko isejoba Aare ana, Oloye Olusegun Obasanjo ni eleekeji, Asiwaju Ahmed Tinubu nikan lo ku to n se egbe oselu  “Action Congress” sugbon lonii, egbe naa lo n dari orileede. Eyi ko je ki eru o ba mi pe emi nikan ni egbe PDP ni gbogbo South West. Bi mo tile se n ba lo yii, mo maa di Aare tabi igbakeji Aare ni orileede yii.

Awon oniroyin tun luu logo eni nipa ikorira to ni si Aare Buhari, Fayose si da won lohun pe oun ko korira Buhari rara, ooto ore ni ko je ki awon eniyan kan gba temi. Lati ibere pepe ni mo ti n forere re pe Buhari ti dagba ati pe ko lokun ninu fun isejoba Naijiria. Se oro mi ri bee bayii abi ko ri bee? Awon kan tile ni nitori aseju mi ni won ko fi je ki n tele awon gomina to lo London lo sabewo sii.. Loooto lo wu mi lati lo, sugbon nigba ti awon to n dari lilo naa ni elomiran lo maa soju egbe,  mo si gba bee.

Foyose ni loju toun, ko si ija ninu oro naa, nitori pe awon kan ti mo pe oun ko le pa iro bi o ti wule ki o kere mo. Ohun ti mo ba ri lohun naa ni maa so faraye, o si tun ni ki awon oniroyin ma se si oun gbo, o ni oun ko ni oniro ni gbogbo awon to lo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…