Home LÁGBO ÀRÍYÁ Ọmọ mi ló ní kí n fẹ́ Funkẹ Akindele – JJC.
LÁGBO ÀRÍYÁ - August 2, 2017

Ọmọ mi ló ní kí n fẹ́ Funkẹ Akindele – JJC.

Akọrin ọmọ orilẹ-ede Naijiiria ti o tun-un ya fiimu, ọgbẹni Abdulrasheed Bello ti gbogbo eeyan mọ si JJC gẹgẹ bi a ṣe mọ pe ọkọ Funkẹ Akindele ni. Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun ni Playgroung TV, JJC jẹ ka mọ pe ọmọ oun obinrin ni o rọ oun lati fẹ Funkẹ Akindele.

O sọ pe o ti pẹ ti oun ti mọ Funkẹ Akindele ati pe awọn ọmọ oun maa n ri ni ayika oun ni gbogbo igba ti wọn si ṣakiyesi pe gbogbo igba ti Akindele ba ti wa layika oun ni inu oun maa n dun. O sọ siwaju pe bo tilẹ jẹ pe orilẹ-ede miran ni awọn ọmọ oun wa, awọn ṣi maa n fi wọn si iṣẹ ojoojumọ awọn.

JJC sọ pe ni akọkọ, awọn ọmọ oun o mọ pe oṣere ni Akindele nitori wọn o ki n wo ere Yoruba. Amọ wọn fẹran ẹ gan. O ni oun ranti nigba ti ọmọ oun obinrin sọfun oun pe oun gbọdọ fẹ Akindele nitori o ma mọ nnkan tọju. Eyi to tumọ si pe o ma le tọju baba awọn. Oun si gbọ si i lẹnu, o ni orin oun ‘saẹe the last dance’ (tọju ijo ikẹyin) ni oun kọ fun aya oun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…