Home iroyin Ogun Badoo: Àwọn ará Ìbèṣè ṣe ìwọ́de.
iroyin - August 2, 2017

Ogun Badoo: Àwọn ará Ìbèṣè ṣe ìwọ́de.

Lenii ọjọ iṣẹgun ọjọ kini oṣun kẹjọ ni awọn ara ibeṣe ṣe iwọde lọ si ile Ayangunreẹn. Ohun to fa sababi ni ogun badoo ti ko lọ nilẹ, ojoojumọ ni wọn n ṣoro amọ eyi o dẹkun iwa ipaniyan ti awọn badoo wọnyi.

Ohun to fa iwọde ọhun gan gan ni pe awọn badoo tun pa mọlẹbi run ni ilu ibeṣe ni ikorodu ni ọjọ aiku. Eyi lo mu ki awọn olugbe agbegbe naa ṣarawọn jọ ti wọn si lọ fi ihonu han ni ile Ọba.

Ta ba ṣakiyesi, a ma ri pe Ọba ko da si ọrọ badoo naa eyi to n kọ awọn eniyan lomi inu. Nnkan ti a gbọ to dasigbẹyin ni ipade ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun fi ju ọwọ silẹ pe awọn o ni da rogbodiyan silẹ mọ. Bo ya ti kabiyesi ba le da si ọrọ badoo naa, gbogbo rẹ le ni iyanju. Awọn ara ikorodu ati agbegbe rẹ a le pa oju mejeeji de ti wọn ba n sun.

Ipade n lọ lọwọ nigba ti a n ko iroyin yi jọ, a ma jẹ kẹ mọ abajade ipade naa ni kete ti wọn ba ṣetan.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…