Home iroyin Ìdí tí Ambode fi ń káàkiri ilẹ̀ Yorùbá
iroyin - August 2, 2017

Ìdí tí Ambode fi ń káàkiri ilẹ̀ Yorùbá

Laarin oṣun to kọja a ri pe gomina ilu Eko ṣe n ṣabẹwo si awọn gomina clcgbẹ ẹ toku ni apa iwọ-orun. Gomina Ambọde ni a ri to lọ si ipinlẹ Ọṣun, Ọyọ ati Ogun. Idi abajọ to jade ni pe gomina Ambọde fẹ da ile-iṣẹ to n ṣe irẹsi silẹ, o si fẹ ki awọn gomina toku pawọpọ pẹlu oun ṣe bi Yooba bọ wọn ni ‘ọwọ kan o gbẹru de ori, agbajọ ọwọ la fi n sọya’.  O pe awọn ipinlẹ toku ki apa iwọ-orun le jẹ ọga nipasẹ pipese irẹsi fun orilẹ-ede Naijiiria ati agbaye lapapọ.

A mọ eyi latari abẹwo ti Gomina Akinwunmi Ambọde  ṣe si orilẹ-ede Switzerland. Iroyin gbe pe o tọwọbọ iwe-adehun pẹlu ile-iṣẹ kan ni Zurich. Ile-iṣẹ naa, Buhler AG ni o ma ṣe awọn ẹrọ to ma yọ kanda kuro ninu irẹsi.

Ninu ọrọ gomina Akinwunmi Ambọde lati gbọ pe ile-iṣẹ yi ma pese iṣẹ to n lọ si bi ọgọrun meji lọna ẹgbẹrun atipe apa iwọ-orun ma di ọga nipa pipese irẹsi. O ni ile-iṣẹ yi ma le pese irẹsi toto mejilelọgbọn tọọnu lojumọ.  O ni awọn gomina toku ma pese ilẹ ti wọn yoo gbin irẹsi naa si.

Gomina Ambọde sọ siwaju pe ile-iṣẹ Buhler yi ni yoo kọ ibi ti wọn yoo ti maa fọ irẹsi naa atipe awọn kan naa ni yoo ṣaboju to. Agbegbe imọta ni ilu ikorodu ni gomina sọ pe ile-iṣẹ naa yoo wa, yoo si gba to ilẹ eka mejilelọgbọn. Oṣun mejila ni yoo gba wọn lati fi kọ ile-iṣẹ naa tan, yoo si jẹ ile-iṣẹ to tobi julọ lorilẹ ede Naijiiria.

Awọn to tẹle Gomina Akinwunmi Ambọde lọ orilẹ-ede Switṣerland ni; kọmiṣọna fun inọwo, ọgbẹni Akinyẹmi Aṣede; olugbani lamọran nipa irin oke okun ati idaṣẹ silẹ, ọjọgbọn Ademọla Abas; kọmisọna fun ọgbin Ọnarebu Suara Oluwatoyin; akọwe ajọ ọgbin, ọmọwe Olayiwole Onasanya.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…