Matic darapọ̀ mọ́ Manchester United.
Lọjọ aje ọsẹ yi ni Nemanja Matic tii ṣe agbabọọlu Chelsea darapọ mọ ikọ Manchester United eyi ti Jose Mourinho jẹ akọni-mọọgba ẹ. Manchester ra Matic ni ogoji miliọnu pọun.
Agba-bọọlu naa tọwọ bọ iwe-adehun ọlọdun mẹta, o ṣeeṣe ko fi ọdun kan kun. Mourinho sọ pe ‘agba-bọọlu Manchester United ni Matic, agba-bọọlu oun Mourinho si ni pẹlu’. O ni agba-bọọlu naa duro fun gbogbo ohun ti awọn n wa lara agba-bọọlu. O dupẹ lọwọ Matic tori wipe o gba lati darapọ mọ awọn.
Matic fun’ra ẹ sọ pe inu oun dun lati darapọ mọ Manchester United ati lati tun ba Mourinho ṣiṣẹ lẹẹkan si. O ni oun gbadun asiko ti oun lo ni Chelsea. O sọ siwaju pe oun ti ṣetan lati mọ awọn akẹgbẹ oun ni Manchester United ati pe ọkan oun ti wa lọna lati gbaradi pẹlu wọn fun saa yi.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…