Home iroyin Nítorí àwọn ajínigbé, àwọn Ọlọ́pàá kún òpópónà.
iroyin - July 31, 2017

Nítorí àwọn ajínigbé, àwọn Ọlọ́pàá kún òpópónà.

Ọga pata pata ti awọn ọlọpaa ni a gbọ pe o ti paṣẹ fun awọn ọlọpaa ni ipinlẹ kankan ni orilẹ-ede Naijiiria lati kọja si oju popona. Awọn ọga ọlọpaa ipinlẹ ti aṣẹ naa kan gbọn-gbọn ni awọn to wa ni opopona Abuja-Kaduna-Zaria.

Agbẹnusọ fun ọga ọlọpaa, CSP Jimoh Moshood ni o sọ lanọ ni ipinlẹ Abuja pe awọn gbe igbese yi lati ri si aṣeyọri eto fifọ ọna mọ-ọn latari ohun to ma n ṣẹlẹ si awọn arinrin-ajo. Atipe eyi ni lati ri pe awọn to ṣẹ ni igbega lọnu iṣẹ ma ni oye iṣẹ ti wọn fẹ ṣe.

Ni nu iroyin kan naa yi lati gbọ pe ọga ọlọpaa patapata Ọgbẹni Ibrahim Idris ti fun ọgbẹni Idris Musa ni igbega. Moshood jẹ ka mọ pe eyi waye nitori ipa ti ọgbẹni Musa ko ninu iṣẹ ọlọpaa nigba ti o wa laye.

Ajọ oniroyin lo jẹ ka mọ pe ọgbẹni Musa ku ni ọjọ kẹrinlelogun oṣun keje ọdun ta wa yi latari egbo to ni nigba ti awọn boko haram kọluwọn ni ipinlẹ Kano ni ọjọ kẹtalelogun oṣun keje.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…