Home LÁGBO ÀRÍYÁ Àwọn ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Obesere
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 30, 2017

Àwọn ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Obesere

 

Ohun ti opo eniyan mo Abass Akande Obesere mo ni orin Fuju ti Asakasa. Won mo o gege bi Omo Rapala ati akoko onifuji to koko se jeri sori.
Sugbon awon nnkan kan wa ti won ko mo nipa re.

1. Lona kinni, bi o tile je pe Obesere maa n be gija-gija to ba n sere lowo, onisuuru eeyan ni to ba ti sokale lori itage.

2. Bi o tile je pe o maa n se bi eni to ti mugbo ati paya yo, Obesere kii muti, kii mu siga.

3. Bi o tile je pe o maa n korin yodi-yodi, Obesere feran lati maa gbe esin Islam ga. A gbo pe o ko mosalasi kan si ile re ni Eko.

4. Won ni o loju aanu gidigidi, ati pe o maa n fun eniyan lowo.

5. O ti to odun mewaa seyin to ti ko ile fun iya re ni ilu Ibadan.
6. Nigba ti opo akorin ni iyawo pupo, a gbo pe iyawo kan soso ni Obesere ni. Oruko obinrin naa ni Alhaja Tolani Akande Abass.

Ni ojo Jimoo si Satide, Obesere fi ife nla han si iyawo re yii nigba to ki obinrin naa ku oriire ojo ibi re. O ni oun ko le fi oro Alhaja naa sere rara tori o duro ti oun lojo didun ati lojo kikan.

 

Lati fi ife nla to ni si obinrin naa han, Obesere ti ko ile nla kan fun un.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…