Home Orisirisi PARIS CLUB: Ayé ń retí bí àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá yóo ṣe náwó gọbọi tó sẹ̀sẹ̀ tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́
Orisirisi - July 29, 2017

PARIS CLUB: Ayé ń retí bí àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá yóo ṣe náwó gọbọi tó sẹ̀sẹ̀ tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́

Opo eniyan lo n wo oju awon gomina kaakiri ipinle Yoruna bayii, lori owo nla nla ti ijoba apapo sese  pin fun won.

Owo naa ti won n pe ni Paris Club Refund je ipin won ninu opo bilionu ti ajo Paris Club to maa n yani lowo da pada fun Naijiria, leyin ti Naijiria si owo naa san fun won ni asanle ni nnkan bii odun mejo seyin.

Gbogbo ipinle to wa ni orile-ede yii lo gba owo naa, to si je pe awon bii Rivers, Kano ati Delta lo gba ju, ti owo won wo bilionu mewaa mewaa.

Ni ile Yoruba, Ipinle Eko lo gba ju. O gba owo to le ni bilionu mejo naira.

Ipinle Oyo ati Ondo lo powo le won nipa gbigba eyi to le ni bilionu meje meje.

Olorun fi bota si buredi Gomina Rauf Aregbesola naa, tori owo to bo si Osun lowo le ni bilionu mefa daadaa, nigba ti Ekiti to gba kere julo gba owo to le ni bilionu merin.

Nnkan idunnu nla gbaa ni eyi je fun awon ijoba naa.

Idi ni pe owo naa dab ii ebun, tabi ohun ti Bibeli pe ni manna to jabo lati orun wa.

Eekeji ti won yoo si gba iru owo bee niyi.

Idunnu nla lo ye ko jefun awon eniiyan naa, tori ipinle ti iri bilionu bee ba wole si, o ye ki won mo pe owo wole sibe.

Idi ni pe bi a se so pe owo Naijiria ya yeye to yii, bii ti bilionu ko.

Ninu bilionu kan, a  maa ri ogorun milionu naira lona mewaa. Omi to ba mo niba ni a maa n figba gbon ni.

Sugbon eru ti bere sii ba opo eniyan kaakiri awon ipinle naa bayii, paapaa ni awon ibi ti won ti je gbese bii Osun, Ondo, Oyo ati Ekiti.

Ibeere ti o joba lokan opo awon osise ni pe: Nje awon gomina yii yoo san owo ti won je osise?

Bakan naa, awon ara ile kan naa n wo o le, loooto, o ye ki ijoba san gbese to je, sugbon won n so pe iru owo to to bayii, osise ijoba nikan ko lo ye ko na a.

Opo kongila naa ni ijoba je lowo. Opo nnkan amayederun lo ye ki won fi owo si, bee ko ye ki ijoba maa na owo ni anatan, ko se e ni orokusu-da-waiwai.

Ko pari sibe. Awon eniyan tun n beru pe bi won ba fi oko (hoe) le were lowo, odo ara re ni yoo rook si. Won gba pe iwa jegudujera wa lowo awon gomina kan. Iberu w ape awon kan le se owo naa basubasu ninu won. Kii kuku se pe won ko maa ri owo losoosu tele, won kan n na a bo se wu won ni.

Idi niyii ti awon osise ijoba ati awon to ti feyinti, to je pe ebi n pa  won latari bi ijoba se je won lowo, se n mura ija sile pe gomina yowu to ba se monamona, ija nla ni awon yoo ba a ja.

.Iru awon ipinle ti oro kan julo ni Osun, Ondo, Ekiti ati Oyo.

Ni Osun Aregbesola ti n san aabo owo osu fun awon logaa-logaa osise, o ti pe die. Eyi je ki gbese o ti po nibe. Ojoojumo si ni awon to ti feyinti n fi ehonu han kaakiri, tori ijoba n febi aisanwo osu pa won.

Wahala ti Rotimi Akeredolu ni Ondo, eni to gba ipo lowo re, iyen Segun Mimiko, lo da a sile. Oun lo je opo gbese sile ko to lo. Oran naa wa di ti Akeredolu bayii, to si da bi pe o fe so eni eleni di Akerejewo!

Opo eniyan lo tun ni ireti pe pelu owo ti Oyo ati Osun ti ri gba yii, boya won a se ohun to ye ki won se lori fafiti Ladoke Akintola University of Technology to wa ni Ogbomoso.

Yunifasiti naa ti fee daru patapata tori awon osise, to fi mo awon olukoni, ko ri owo osu gba lati ojo pipe.

Bayii, Gomina Ayo Fayose nikan lo tii so ohun to jo gbedeke lori bi o se fen a owo naa.

Ninu ipade kan to se pelu awon osise ijoba ati awon araalu miiran ni Ado Ekiti, o ni yunifasititi ipinle naa, awon osise feyinti ati awon osise ijoba yoo ni ipin ninu re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…