Home Orisirisi Faleti máa ń jẹ àmàlà àti gbẹ̀gìrì lẹ́ẹ̀mẹta lójúmọ́ – Ìyàwó olóògbé
Orisirisi - July 29, 2017

Faleti máa ń jẹ àmàlà àti gbẹ̀gìrì lẹ́ẹ̀mẹta lójúmọ́ – Ìyàwó olóògbé

Iyawo Alagba Adebayo Faleti, Iyaafin Abosede Faleti, ti se’ranti ibagbepo ayo ti oun ati oloogbe naa gbe.

Obinrin naa ni awon nifee ara awon debi pe bi Faleti ko bat ii dari dele, oun kii jeun ale. Bi oun naa ko ba si tii setan, Faleti naa kii jeun. O ni awon jo maa n jeun papo ni.

O wa se alaye pe awon jo maa n wo aso ara awon, debi awotele naa.

Lori ounje ti Faleti feran ju, oro agba osere naa da bii ti ewe to pe lara ose to dose.  Omo Oyo Alaafin ni loooto, sugbon Ibadan lo gbe ni gbogbo aye re. Ti a ba si n soro ounje ti Ibadan feran ju, a ko le yo amala kuro.

Gege bi iyawo re se o, Faleti feran amala ati gbegiri debi pe o le je e leemeta lojumo.

Bakan naa o feran eran dindin ati akara elepo.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…