Home iroyin Femi Fani-kayode pe Femi Adesina lónírọ́
iroyin - July 23, 2017

Femi Fani-kayode pe Femi Adesina lónírọ́

Femi Adesina ni Oluba Aare Buhari damoran nipa iroyin nigba ti Femi Fani-kayode je Minisita tele fun eto oko ofurufu. Adesina lo salaye nibi ero ayelujara Twitter re pe, gbogbo awon to n bu Aare Buhari leyin ni won tun maa wa rerin-in eke fun baba naa to ba de lati oke okun to ti lo toju ara re.

Fani-Kayode wa ni oniro gan-an ni Adesina ati awon egbe re nitori pe ko si bi baba naa se le de ti agbara re a tun gbee lati maa dari Naijiria mo, sugbon eyin oniro maa ti baba naa ni itikuti pe saka ni ara, ati wi pe ki o maa se ijoba re lo.

Oro lori ailera Buhari yii lo n fa itakuroso laarin awon agba meji. Fani-Kayode tun te siwaju nipa sisalaye pe nnkan meji lo ye ki egbe Adesina maa kabamo bayii, awon naa si ni Buhari ti ko gbadun ti won gbe ise Naijiria ko lorun ati Ogbeni Rauf Aregbesola ti won gbe sile gege bii gomina ni ipinle Osun.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…