Home Orisirisi  Àsírí owó Ọmọtọla: Ó ti ra gbogbo ilé tó wà ní pópónà kan ní Ikeja
Orisirisi - July 23, 2017

 Àsírí owó Ọmọtọla: Ó ti ra gbogbo ilé tó wà ní pópónà kan ní Ikeja

Eni ti ko ba mo ibi ti egbe re ti n la, ere asaku ni oluware yoo sa.
Opo awon osere tabi alariya to kan n be gaugau kaakiri ati awon ti won n lu jibiti lati lee se afeaye, won ni lati lo ko eko pataki lodo gabjugbaja osere fiimu, Omotola Jalaade-Ekeinde.
Omotola ti se alaye bi oun se di olowo ati onise okowo ti ko see fi owo ti segbe kan. Ninu iforowanilenuwo pataki kan to sese se, o ni orisiirisii ise ni oun n se, bi o tile je pe onifiimu ni oun. Omotola ni pataki lara awon ise bee ni ile rira ati tita, ti awon oloyinbo n pe ni real estate.
O se apere bi oun se n ra ile bi eni ra recharge card ni adugbo kan to je pe awon olowo lo po nibe, iyen Mobolaji Bank Anthony Way. O fi kun un pe bayii, oun ti ra gbogbo ile to wa ni popona (street) kan, ti oun sit un ti fo si ibomiran.
Omotola wa da awon akegbe re to n sise alariya nimoran pe won ni lati wa ise miiran maa se kun ohun ti won n se. O ni gbigbajumo ti won gbajumo ni yoo je ki iru ise bee lere pupo.
Bi Omotola se wa lowo to, o ni oun gbagbo pe okunrin lo gbodo maa gbe bukaata inu ile. O dupe pupo lowo baale re lori bo se duro ti i lati igba ti won fe ara won ni 1995.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…