Home Orisirisi Ibo ijoba ibile Ipinle Eko: Gbogbo oju wa lara Tunde Babawale
Orisirisi - July 22, 2017

Ibo ijoba ibile Ipinle Eko: Gbogbo oju wa lara Tunde Babawale

 

 

Eto idibo ijoba ibile ti Ipinle Eko to n waye lonii ti ko opo eniyan laya soke. Leyin awon oloselu to n sa sotun-un ati osi, ati awon omoleyin won to n sa kijokijo, awon araalu gan-an n gbadura nip e ki ibo naa tete waye, ko si pari layo.

Bi won ko tie tori nnkan miiran gbadura, won fe tete pada si ibi ise won ati awon ibomiiran ti won fe lo. Idi ni pe ijoba ti sofin pe eni kankan ko le jade lo ibi kankan lati aago meje aaro di aago merin irole.

Awon amoye mo pe aseyori ibo naa wa lowo ijoba, awon agbofinro, awon oloselu ati ajo eto idibo. Ohun ti opo eniyan ko wa mo ni amodunju ni iru eniyan ti okunrin to n dari ibo naa je. Oun naa ni Ojogbon Tunde Babawale, to je Alase Eto Idibo ni Eko.

Nigba ti Gomina Akinwunmi Ambode yan Babawale si ipo naa ni aipe yii, opo awon to mo o ni amodunju lo kan saara si gomina. Won ni o sere bee, bee ni omokunrin se. Won ni o fi opolo se eto naa, ti won si so pe o moju lo si oja, to si je pe eni rere lo mu de.

Gbogbo ibi to ti sise, aseyori nla nla lo maa n se. Bi apeere, lati odun 1991 lo ti n se ise olukoni ni University of Lagos, iyen fafiti ti ilu Eko, to wa ni Akoka. Ko pe pupo leyin to kekoo gboye ni Obafemi Awolowo University to bere ise nibe. UNILAG naa lo ti sise-sise, to kawe-kawe to fi di koofeso nla fun oro oselu to mu oro aje dani, iyen Professor of Political Economy.

Lara awon aseyori nla ti Babawale se ni gbigbe ajo Centre for Black and African Arts (CBAAC) goke agba nigba ti ijoba Olusegun Obasanjo yan an gege bii olori ibe. Odun mejo gbako lo lo nibe, ti ko si mu abaawon kankan lowo.

Ki Babawale to de CBAAC, ibe ko ni laari. Bee ibe ni won ko opo ohun isenbaye gbogbo adulawo si. Sugbon kete ti o de ibe, p bere sii se opo akitiyan ni. Akitiyan naa mu ki irawo CBAAC tan kaakiri agbaye, to si di ohun ti opo omowe, agbasaga, ile eko ati ile ise n ba se.

Ko pe ti o kuro nipo ni o pada si UNILAG, ti won si tun gba a towo-tese. Ibe lo tun ti di oga agba ni eka to n ri si idagbasoke ati aabo awon omo ile iwe – students affairs.

Babawale mo bi a se n fi ogbon, imo ati oye se eto. O si mo bi a se n gbe oro kale pelu laakaye. O je eni kan ti kii figba kan bokan ninu. Idi niyi ti opo fi gba pee to idibo ijoba ibile naa, aseyori ni yoo se e.

Omo bibi ilu Inisa, ni Odo Otin Local Government Area ni Tunde Babawale. Ibe naa lo si ti ka iwe alakobere ati girama, ko to bo si yunifasiti ti Ile-Ife.

Nje Babawale yoo le se bi o se maa n se tele, nipa sie eto to peye, to si le mu aseyori nla wa? Gbogbo oju wa lara re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…