Home òpómúléró   Idi ti Wole Soyinka kii fii ge irun ori re (Oni ni ojo ibi re…)
òpómúléró - July 21, 2017

  Idi ti Wole Soyinka kii fii ge irun ori re (Oni ni ojo ibi re…)

 

… o pe eni odun metalelogorin (83 years) lose to lo

Pelu ogo Olorun,  ogunna gbongbo laarin awon akowe ati omowe, Ojogbon Wole Soyinka, di eni odun metalellogorin (83 years) lose to lo.

Idi ni pe ojo ketala, osu keje odun 1934 ni won bi i.

Gbogbo bi ikini ku oriire se n lo lotun-un losi kaakiri agbaye ni orisiirisii foto Soyinka n yoju sode.

Awon kan se afihan irinajo re kaakiri agbaye. Awon kan ranni leti igba to gba oye oataki ti a mo si Nobel laureate for Literatutre ni odun 1986. Bee, awon kan fihan wa bi Soyinka se ri nigba to wa ni ewe ati awon ara to da – se agba wa bura bi ewe ko se e ri.

Ninu opo awon foto naa, ohun to si n ya opo eniyan lenu ju ni irun funfun gagara ti Soyinka pe jari bi ade egbon owu.

Opo eniyan ni enu maa n ya pe o se je ti Soyinka kii ge irun ti?

Sugbon sa o, o ti se alaye idi ti oun fi fi irun naa sile.

Ninu iforowanilenuwo kan, Soyinka ni nigba ti oun je omo ile iwe ni yunifasiti ni orile-ede England, owo ti awon agerun (barber) n gba ti poju. Kii sii se gbogbo igba ni oun maa n fe san iru owo bee. Nipa bee, o bere sii fi irun naa sile lori oun. Bi alaborun se di ewu niyi, ti irun funfun gan-un-gan-un se gba ijoba lowo onkowe naa.

Lona miran ewe, ibaje naa maa n di ewa. Idi ni pe irun naa tun di ohun ti opo eniyan mo mo Soyinka.

Soyinka tun so pe nigba ti oun tun wa dagba, ti oun n kowe lemolemo, ti oun si tun n sise kaakiri yunifasiti, oun kii raye lati gerun. Idi niyi ti irun naa fi wa bo se wa, to si je pe o daju pe bi yoo se maa wa naa  niye.

Sugbon a gbodo fi kun un pe lojo kan, Olorun lo yo Soyinka nigba ti ina lanta to gbe lowo ran mo irun naa.

AKIYESI: Oni ni Ojogbon Wole Soyinka pe odun merinlelogorin (84 years) lori ile alaaye…

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…