Home Orisirisi Mo máa ń kọ́ Davido ní ijó jíjó – Senito Ademola Adeleke
Orisirisi - July 20, 2017

Mo máa ń kọ́ Davido ní ijó jíjó – Senito Ademola Adeleke

Senito tuntun ganin lati Osun, Ademola Adeleke , ti soro lori bi o se maa n jo bi okoto.

O ni ebun ti Olorun fun oun ni ati pe oun maa n fi se ere idaraya, ti oun si maa n lo ijo lati je ki ife wa laarin molebi, ara ati ojulumo oun.

O tun so pe lasiko ipolongo ibo, ijo jijo ati ariya maa n sise fun awon oludije.

Ni pataki, o ni oun maa n ko awon omo oun mejeeji ti won n korin, ati omo egbon oun, Davido, bi a se maa n jo.

Fidio awon ijo ajoran bi okoto to jo lenu ojo meta yii wa kaakiri. Bakan naa ni eyi to ba olomoge kan jo ati eyi to jo fun Davido ninu fideo re.

Senito Ademola ti wa se alaye pe omo bibi inu oun ni omobinrin ti oun ba jo ninu okan ninu awon fideo naa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…