Home iroyin Àwọn awakọ̀ tírélà fìbínú dáná sun báǹkì méjì
iroyin - July 19, 2017

Àwọn awakọ̀ tírélà fìbínú dáná sun báǹkì méjì

Ede aiyede lo waye laarin awako tirela kan ati olopaa to n so ile ifowo-pamo-si ni agbegbe Apapa to wa l’Eko. Awako yii gbe oko re di iwaju ile ifowo-pamo-si ti awon olopaa n so, ni eyi to mu ki olopaa naa yari pe awako naa ko gbodo fi oko si iwaju ile-ifowo-pamo-si sugbon awako naa ko jale, o fi moto naa sile, o si fa kokoro yo.

Inu bi olopaa okan ninu awon olopaa naa, gbogbo ihale to se fun awako yi dabi igba ti aja n gbo lasan tabi ti eniyan n yin agbado seyin igba, bi inu se bi olopaa niyi to fa ibon yo pelu ireti pe awako naa a sare lo gbe oko re. “Ibinu ko kuku mo pe olowo ohun ko lese nile”, ibon ba dahun lowo olopaa naa, bi awako naa se lule niyi ti o si je Olorun nipe loju ese.

Awon akegbe re to ku fa ibinu yo, won lee, sugbon owo won ko tee, o sare wo ile ifowo-pamo-si, awon awako ni ki won tii jade ki awon le da seria owo awon fun un sugbon Banki naa ko lati tii jade ni eyi to mu ki awon awako naa fabinu yo sodi. Won dana sun Banki naa ati eyi to wa legbe re. Oro naa di isu ata yan-an, yan-an ni owuro oni lagbegbe Apapa. Lati igba ti ija naa ti sele ni awon ara agbegbe naa ti n te atejise fun gbogbo awon eniyan ti won ba mo lati ma se gba adugbo naa rara. Awon olopaa digbo-luja ti petu si aawo naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…