Home LÁGBO ÀRÍYÁ Okoye fẹ́ kó bá Psquare
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 18, 2017

Okoye fẹ́ kó bá Psquare

Ijoba apapo lo sofin pe gbogbo atejade orin ati fiimu alagbelewo pata ni ki a maa pari ni orileede wa. Minisita fun eto iroyin ati asa, Alhaji Lai mohammed lo kede re laipe yii.

Ikede naa ni o bi Peter Okoye to je okan ninu awon olutele Psquare ninu to fi n yo suuti ete si ijoba apapo, o ni ijoba apapo ko mo ohun to kan ati pe kin ni o kan won pelu ibi ti elere tabi olorin ba ti fe pari ise re?

Ijoba apapo si ni awon se eleyii lati pese ise repete fun awon odo. Ijoba ni gbogbo eto lo ti fere to tan ti ko ni je ki awon olorin ati elere maa ko owo ile rode.

Gbogbo ohun ti okoye n so lo n bi awon egbe kan to je ololufe egbe APC ninu ti won fi n gba ijoba apapo nimoran pe ki won fi owo sinkun ofin mu okorin Hiphop naa, nigba to je pe eni to ba ju ni lo, le ju ni nu. Awon ololufe APC yii tun pa itan fun Peter Okoye pe nibo ni oun ati Psquare wa nigba ti ijoba apapo sofin ni odun 1999 pe gbogbo ileese Redio ati Telifison gbodo maa lo awo orin to ba je ti omo Naijiria ni igba ida marundinlogorun-un (95%), ki won si maa lo ida marun-un (5%) pere ninu eyi to je orin ti ile okeere. “Ogede lo wo koko ye tan ko to di igi buruku” lodo Peter Okoye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…