Malala s’àbẹ̀wò sí Nàìjíríà
Odomodebinrin to maa n ja fun eto omoniyan, ti ko tii ju omo ogun odun lo sabewo si orileede yii ni nnkan bii aago marun-un aabo irole ana ojo Aje. Adele Aare ile wa, OjogbonYemi Osinbajo ni o gbaa lalejo ni ile ijoba to wa ni Abuja.
Malala yii kan naa ti wa ri ni odun 2014, Omowe Goodluck Jonathan ni o wa lori aleefa ni igba naa. Arabinrin yii wa nitori awon omobinrin ileeewe Chibok ti won le nigba, ti awon Boko Haram ji ko lati igba naa.
Eto Eko orileede yii to n polukurumusu ati awon omo Chibok ti ko tii de tan je ohun to je arabinrin yii logun ju. O si salaye fun adele Aare pe gbogbo ohun to ba maa nan ijoba ni ko nan won, a ni lati gbe eto eko dide pada.
Omo orileede Pakistan ni Malala, o si ti gba ami eye “Nobel Peace Prize Winner” ri. Alagba Yousafzai to je baba re pelu awon ti won jo wa ninu egbe ajajagbara ti kii se ti ijoba “Malala Foundation” naa tele wa si Naijiria.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…