Home Orisirisi Àríyànjiyàn ńlá: Femi Adebayo ní òun kìí ṣe ẹgbẹ́ Odunlade Adekola nínú fíìmù síse
Orisirisi - July 17, 2017

Àríyànjiyàn ńlá: Femi Adebayo ní òun kìí ṣe ẹgbẹ́ Odunlade Adekola nínú fíìmù síse


E gbo na, ta ni eyin gba pe o mo ere fiimu se julo laarin Femi Adebayo ati Odunlade Adekola? Ohun ti a n so ni sisere (acting) ni ilana to gbayi julo; ni ona ti yoo mu ki ori eni to n wo fiimu o wu, ko si da bi wi pe ki fiimu naa ma pari mo.
Femi Adebayo lo da ariyanjiyan yi sile ninu iforowanilenuwo kan. Won bi i pe laarin oun ati Adekola, ta lo gba pe o mo fiimu se ju.
Femi ko besu begba, ko ro o leemeji, o ni oun kii se egbe Adekola ninu ere sise. O ni ti won ba ko awon mejeeji sile, ti won si ni ki oun mukan, Femi Adebayo ni oun yoo koko mu.
Oro yii ti da ariyanjiyan nla sile. Awon kan ni Femi ko paro, nigba ti opo eniyan ni Odunlade mo ere se ju u lo.
Ni ti eyin, ta awa le yan laayo?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…