Home iroyin Wọ́n sépè ìdí ńlá fún mi ni
iroyin - July 16, 2017

Wọ́n sépè ìdí ńlá fún mi ni

Ohun to koju si enikan, eyin lo ko si elomiran, eyi lo difa fun arabinrin omo odun marundinlogota kan ti orileede Souh Africa. Gbogbo eya lo gba pe, obinrin to rewa ni lati loju  gun rege,nnkan aya meji to duro daadaa, eyi to kan naa ni idi to ye ko yo sita ju ti okunrin lo.

Eru idi yii ni olori isoro Mamashi Oageng, o ni, ni nnkan bii odun mefa seyin, oun le rin daadaa, bi o tile je pe awon eniyan maa n pe oun ni orisiirisii oruko lati fi oun se yeye, sugbon bi oun se n fi ebi panu to ki idi le wale ni idi tun n yo sita sii.

O ni gbogbo odo awon onisegun oyinbo ni oun ti de ti won ni ko si ogbon kankan ti awon le da sii. Idi ti wa po de bii wi pe, o ni ko je ki oun le yara se ohunkohun mo. O ni koda, lati we ni ohun lara. O ni oun maa n lo opo asiko lori ibusun ohun nitori inira to wa ninu ki oun maa rin kiri.

O ni oro idi naa le de bi wi pe awon okunrin ko fe gbe oun ni iyawo wole won, amo won kan fe maa fi idi oun sere lasan ni. O tile pinnu lokan re pe oro idi naa o ki n se ojulasan, o ni o dabi eni pe o lowo aye ninu.O ni inu oun ti maa dun ju ni ojo ti ona abayo ba lo wa fun idi naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…