Home Orisirisi Ó kàsìàrà! Salawa Abeni ni ààyò Dino Melaye
Orisirisi - July 16, 2017

Ó kàsìàrà! Salawa Abeni ni ààyò Dino Melaye

 

Lenu ojo meta yii, orin aguda Ajekun-unya ni yoo je ni opo eniyan mo asofin agba Dino Melaye mo. Orin naa lo gbe e jade, gege bi Talaso se gbe Wasiu Ayinde saye, ti Ace gbe Shina Peters saye, ti Bonsue si gbe Adewale Ayuba saye.

Sugbon sa o, IROYIN OWURO ti gbo pe orin ti Melaye feran julo ni orin Salawa Abeni.

A gbo pe ko saaba si ojo kan ti kii gbo Salawa, yala ninu ile re ni Abuja ati Kogi ni o, tabi ninu awon moto re boginni boginni.

O fi enu ara re so fun awon eniyan kan pe ninu gbogbo awon olorin agbaye, Salawa Abeni Waka Queen ni aayo oun.

Apere otito inu oro Melaye ni pe ko fee si awo orin Salawa kan ti ko ni.

Loooto, Salawa ni opo ololufe kaakiri Naijiria ati oke okun.

Iru awon eniyan bee ko le gbagbe itu to fi orin waka pa paapaa ni awon odun 1980 si odun 1990 di bii 2000.

Lara awon orin Salawa to gbayi julo ni Indian Waka ati Gentle Lady.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…