Home iroyin   Ìdùnnú subú layọ̀, Yẹmi Elebuibon di ẹni àádọ́rin ọdún (70 years)
iroyin - July 16, 2017

  Ìdùnnú subú layọ̀, Yẹmi Elebuibon di ẹni àádọ́rin ọdún (70 years)

Awon orisa ile Yoruba, paapaa Akere-finu-sogbon Orunmila, yoo maa jo, won yoo maa yo l’orun bayii, tori idunnu to subu layo nile okan ninu awon omo won pataki, Oloye Araba Yemi Elebuibon.
Inu osu yii ni baba agbasaga pataki naa pe eni aadorin odun, eyi to tumo si pe osu kan naa ni won bi oun ati Ojogbon Wole Soyinka.
Elebuibon je omo Yoruba atata. Opomulero ni ninu awon ti ko tii je ki asa ati ise Yoruba o jona tan.
Gege bi elesin ibile, o maa n ja raburabu ki nnkan atokeerewa ma pa ti baba nla wa mole. O mo Ifa, o maa n gbe Ifa laruge, to si ti se opo ere onise lori itan ati iwa Ifa.
Baba naa lo maa n se Ifa Olokun nigba kan.
Gege bi atejade kan ti onkowe kan, Alagba Jare Ajayi, fi ranse si wa se so, lara awon eto ti won ti la sile fun ayeye ojo ibi ti asekagba re yoo waye ni Osogbo, ni ogbonjo osu yii, ni ipade pelu awon oniroyin lojo kokandinlogun osu keje, idanilekoo ita gbangba lori ipa ti Elebuibon n ko ninu idagbasoke as, ifilole iwe kan ti Elebuibon sese ko – Osundagbonu: the Sole Journey of a Priest . Eyi yoo waye ni ojo kerindinlogbon osu yii.
Nigba ti Elebuibon yoo tun lo be awon omo alainiwo pelu ebun, ogbonjo osu yii ni asekagba ayeye naa yoowaye ni Civic Centre, ni Osogbo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…