Home Orisirisi Owo ba Baale Shangisa to fe lu Ambode ni jibiti, o paro pe won ji oun gbe
Orisirisi - July 13, 2017

Owo ba Baale Shangisa to fe lu Ambode ni jibiti, o paro pe won ji oun gbe

 

Asiri Baale Shangisa, Magodo, ni ilu Eko, to ji ara re gbe, to ni awon ajinigbe lo ji oun gbe ti tu o.

Ojo karun-un osu yii ni iroyin dede kan pe won ti ji baale naa gbe ni adugbo Magodo, leyii to ba opo eniyan leru.

Sugbon iwadii ti awon olopaa se fihan pe iro funfun balau ni okunrin naa to n je Yusuf Ogundare pa. Oun ati aburo re kan to n je Adams, ati awon molebi re miran, ni won jo d’ogbon ewe, ti Ogundare kan sa pamo sibi kan.

Boya o gba pe bi oun ba se bee, ijoba Ipinle Eko yoo tara sasa gbe owo nla jade fun oun ati aburo oun lati pin.

Iwadii ti awon olopaa se lo je ki akara tu sepo.

Gege bi Oga Olopaa ni ipinle naa, Ogbeni Fatai Owoseni, ti so, o ni igba ti awon da ibeere lu awon aburo Ogundare ni ododo foju han.

Pelu ibinu nla ni Gomina Akinwunmi Ambode fi pa a lase ki Ogundare fi ipo Baale sile fungba die na, eyi ti awon oloyinbo n pe ni suspension.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…