Home iroyin À ń dúpẹ́ bọ̀ o, Buhari bá Bisi Akande sọ̀rọ̀ lórí fóònù
iroyin - July 13, 2017

À ń dúpẹ́ bọ̀ o, Buhari bá Bisi Akande sọ̀rọ̀ lórí fóònù

 

O ye ki awon ti okan won ti wa loke lori ilera Aare Muhammadu Buhari je ki okan won wale die bayii o,pelu iroyin kan ti a tun gbo lonii.

Teletele, awon kan ni ailera to n se Aare po debi pe ko le soro mo.

Won ni ese kan aye, ese kan orun ni lapalapa wa, eyi ti awon dokita n pe ni life support.

Sugbon sa o, a gbo pe eni ti won ni ko lee soro lo foonu nigba ti o pe okan lara awon olori egbe APC, Oloye Bisi Akande, to si ba a daro ti iyawo re to ku, Iyaafin Omowumi Akande.

Okan lara awon Olubadamoron lori Iroyin, Mallam Sheu Garba, ni o so oro yi di mimo.

 

 

… sugbon Fayose ko tii fi Aare lorun sile

Ohun ti Gomina Ipinle Ekiti, Ogbeni Ayo Fayose, ati Aare Muhammadu Buhari jo fa po, Olorun Oba nikan lo mo o. Bi Fayose se maa n soro Buhari, afi bi eni pe won gbayawo ara won ni.

Nigba ti opo eniyan si n dunnulori ireti pe ara Aare ti n ya, ati pe ko ni pe pupo mo lati pada si Naijiria, Fayose ti so pe iro funfun balau ni.

O so lojo Alaaruba pe iro ni Ojogbon Osinbajo pa pe oun foju kan Buhari ni London lojo Isegun, ati pe Olorun ti gbakoso lori ilera re.

O wa so fun Osinbajo pe ko fi eri ipade re pelu Buhari han araye.

O ni oun mo pe ara Aare ko tii ya rara. Koda, o ni oun ni awon foto kan lati fihan pe nnkan ti baje.

Lati igba ti Buhari ti n se ipolongo ibo ni Fayose ti maa n so pe ara re ko ya, to si so pe olodi Aare ko nii pe jo Olorun nipe.

Sugbon gbogbo bi Fayose se maa n bu Buhari esi le oro re.

Eyi je ki awon eniyan kan maa ro o pe boya ojo kan n bo ti Buhari naa yoo jewo ara re han gomina naa.

Sugbon, nje Fayose setan lati panumo bi?

Gbogbo oju naa ni yoo ri i.

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…