Home Orisirisi ‘Wákàtí kan péré ni Osinbajo lò pẹ̀lú Buhari ní London’
Orisirisi - July 12, 2017

‘Wákàtí kan péré ni Osinbajo lò pẹ̀lú Buhari ní London’

Bi a ti se n reti ipadabo Adele Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo, si Naijiria lati ilu London, nibi to ti lo se abewo si Aare Muhammadu Buhari lojo Isegun, a ti gbo pe wakati kan pere ni o lo pelu oga re o.
Ohun to fa a ti ipade naa fi kuru bee, a ko tii mo.
Boya awon dokita lo ni ki Osinbajo se kia ni o; boya idunnu pe o ba Aare daadaa ni o; tabi bi o se se pataki fun un lati tete pada si Abuja, tori ko dara pupo ki awon mejeeji fi ile sile. Se ohun ti a ba fi sile ni ewure maa n gbe.
Ile ise iroyin fun orile-ede yii, iyen News Agency of Nigeria, lo so pe wakati kan pere ni awon Aare ati Osinbajo jo lo.
Sugbon sa o, o ni Osinbajo ko tii so hulehule abo ipade naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…