Home LÁGBO ÀRÍYÁ Nínú fọ́tò tuntun, Iretiola Doyle dà bí àsẹ̀sẹ̀yọ osù, gbogbo ayé ló ń bẹjú wò ó
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 12, 2017

Nínú fọ́tò tuntun, Iretiola Doyle dà bí àsẹ̀sẹ̀yọ osù, gbogbo ayé ló ń bẹjú wò ó

 

Eni to ba je arewa lati orun wa, o maa n da bi eni pe ojoojumo ni o maa n rewa sii. Koda, ti yoo fi di agbalagba, awotunwo naa lo maa n je.

Gege bee ni ti osere fiimu pataki ti a mo si Iretiola Doyle. Aipe yii ni o di eni aadota odun, sibesibe, o tun n dan gbinrin loju ni.

Eyi lo fa a ti awon ololufe re fi n sa a ni mesan-an mewaa nigba ti o yo bi osu ninu foto tuntun kan to fi si ori ero alatagba Instagram.

Bi olomoge ni Iretiola tun ri, bee Olorun yonda omo bii mefa fun un.

Orisiirisii oro iwuri ni awon eniyan fi n ranse si i lori foto naa.

Laipe ni iroyin kan tan kale pe ija ti be sile laarin Iretiola ati baale re, Alagba Partrick Doyle, ti oun naa je gbajugba laarin awon osere.

Sugbon Iretiola ko tii soro kan gbogi lori eyi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…