Home Orisirisi Orogún méjì bí ọmọ ìyá láàfin Ọ̀yọ́
Orisirisi - July 11, 2017

Orogún méjì bí ọmọ ìyá láàfin Ọ̀yọ́

Ti a ba n wa oba alade ti o ni iyawo to rewa pupo, ko si bi a ko se ni ka Alaafin ti Oyo, Oba Lamidi Adeyemi, mo won. Kabiyesi ni awon arewa obinrin to see mu yangan lojokojo. Ohun to tun maa n jo awon eniyan loju ni pe olo eleje tutu ni opo ninu awon olori naa.

Lopo igba, kii si irepo laarin awon obinrin meji tabi ju bee lo ti won ba fe okunrin kan naa. Ki baa se ni ile ola tabi ile talaka. Idi niyi ti awon agba se so pe orisa je n pe meji obinrin ko denu.

Sugbon ni ile Iku Baba Yeye, Alase, Ekeji Orisa, awon obinrin meji kan wa ti won le je ki orogun maa wu eniyan an se. Awon naa ni Olori Memunat Omowunmi Adeyemi ati Olori Badirat Olaitan Adeyemi. Eni ogun odun o le die ni awon mejeeji. Eyi to tumo si pe won wa lara ohun to n je ki Alaafin, eni to je eni odun mejidin-logorin (78 years) o si maa se kebe-kebe.

Ni pataki, bi o tile je pe orogun ni won, a gbo pe won ni ife ara won pupopupo.

Gege bi iroyin oniroyin pataki kan se so ni kemiashefonlovehaven se so, ore gidigidi ni awon mejeeji.  Won ko so pe tori pe eni kan naa lo fe won ki won maa se etanu ara won. Won jo n je, won jo n mu ni. Won ni bi won ba tie ni idi kan lati binu si ara won, won kii je ko pe ti won yoo tun fi maa se bi omo iya.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…