Home LÁGBO ÀRÍYÁ Joke Silva dúpẹ́ lọ́wọ́ Olu Jacobs torí ìfẹ́ tó ní sí i
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 11, 2017

Joke Silva dúpẹ́ lọ́wọ́ Olu Jacobs torí ìfẹ́ tó ní sí i

 

Awon gbajumo ti igbeyawo won n daru ni nnkan kan lati ko ninu igbeyawo awon agba osere fiimu meji ti a mo si Olu Jacobs ati Joke Silva.

Won ti jo wa tipe. Ninu ofii, ninu olaa, omo pandoro won ti gbo.

Okookan won lo ti lokiki ninu ise tiata ati fiimu, ti won ti na igbara, ti won ti na igboro.

Sibesibe, igbeyawo won duro digbi.

Kin wa ni ohun ti o ye keeyan ko lara won?

Laipe yii, Joke Silva ni opo suuru se pataki. O tun ro awon loko-laya gbajumo ki won yee ko gbogbo oro aye won sori ero alatagba ti a mo si social media.

Sugbon oro kan ti obinrin naa so lonii ojo Isegun tun se afihan bi nnkan se n dan moran fun oun ati baale re. Oni ni Olu Jacobs pe eni odun marundin-logorin (75 years). Ninu oro ikini ku oriire ti Joke gbe jade fun Olu, o dupe lowo okunrin naa fun ife to ni si oun ati awon omo oun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…