Home iroyin Irinkerindo Dele Momodu: Idi ti ko fi le jeun lojo to ba Osinbajo lalejo
iroyin - July 10, 2017

Irinkerindo Dele Momodu: Idi ti ko fi le jeun lojo to ba Osinbajo lalejo

 

 

Oga agba kan ninu awon oniroyin lorile ede yii, Alagba Dele Momodu, ti se alaye abewo pataki kan to se si Adele Olori Orile-ede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo, lojo Sunday.

Momodu, to je oludasile iwe iroyin OVATION, ni ibi ti ajaga orun Naijiria de lo je ki oun se abewo naa si ibujokoo ijoba apapo, iyen Aso Rock, ni ilu Abuja.

O se alaye pe abewo naa je ki oun ri Ii pe oniwa irele, eni to n fi tokan-tara sise fun Naijiria ati eni ti ko fe iwa ibaje ni Osinbajo.

Momodu ni kii se eni kan to maa n ko olopaa ati soja sodi kaakiri to ba ti wa ni oofisi re, bee o si ni ife ododo si oga re, Aare Muhammadu Buhari.

Momodu ni nigba ti awon fe bere ipade ti awon se ni Aso Rock, won gbe ipapanu, iyen snacks ati  tii (tea) fun awon mejeeji. O ni sugbon nigba ti awon bere sii soro lori ipo ti Naijiria wa ati ibi ti Osinbajo fe ko de, eni kankan ninu awon ko tie ranti fi nnkan kan senu mo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…