Home Orisirisi Rooney, ó dìgbà!
Orisirisi - July 9, 2017

Rooney, ó dìgbà!

 

Tiku ko, tarun ko o,  Rooney n lo ile mii tuntun ni.

Agbaboolu pataki naa, Wayne Rooney, ti n kuro ni Manchester United bayii. O ti di eni ti won n ki kaabo si Everton.

Odun metala gbako lo ti lo ni Man U, to si ba won gba orisiirisii koobu, paapaa nigba ti Alex Ferguson je adari won.

Lenu loolo, yii, nnkan ko senu rere fun agbaboolu naa, to fi je pe opo igba ni adari Man U bayii, Josse Mouriho, kii lo o daadaa.

Sugbon sa o, ti a ba pa emo loko ila, ti a se e sinu ilasa, oko emo naa ni emo lo.

Ile ni Rooney pada si tori Everton naa lo wa tele ki Man U to gba a.

 

Boya bi o ba tie de Everton ese re yoo ji pada. 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…