Home iroyin Oju mi ri mobo lasiko ogun Biafra – Obasanjo
iroyin - Orisirisi - July 8, 2017

Oju mi ri mobo lasiko ogun Biafra – Obasanjo

Aare orile-ede yii tele, Oloye Olusegun Obasanjo, ti seranti ohun ti oju re ri lasiko ogun Biafra.

O ni oju oun ri mobo, to si je pe kii se ohun ti oun le gbagbe laye.

O so eyi ni Ipinle Edo, nigba to n fesi lori bi awon eniyan kan ti n so pe awon fe pin kuro ni Naijiria, ti Obasanjo ri gege bii pe won n ko leta si ogun.

Awon Nnamdi Kanu to n ja ajagbara Biafra labe asia IPOB gan-an ni o ni lokan.

Obasanjo so pe awon ti won n se jagidijagan, won n se bee tori won ko mo ohun to n je ogun ni.

O ni oro ogun da bii owe ti Yoruba maa n pa pe eni ti Sango ba toju re wole ri, ko nib a won bu Oya laelae.

Obasanjo ni wahala ti awon to jasun Biafra foju ri le debi wi pe oun ko lee ba won lo sogun mo laelae.

O wa ro awon omo Naijiria ki won tun ero won pa, ki won wa irepo, ki won si se atunto okan won lori itesiwaju orile-ede yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…