Ẹ̀rù Badoo ń bà mí o – Baba Suwe
Ogbontarigi alawada, Babatunde Omidina ti a mo si Baba Suwe, ti ke gbajare pe akatakiti awon egbe okunkun Badoo ti da opolopo eru si okan oun.
Ilu Ikorodu, ni Ipinle Eko ni Baba Suwe n gbe, ibe si ni awon Badoo naa ti n se ijamba, ti won n pa eniyan bi eni peran.
Ijoba Akinwunmi Ambode ati awon olopaa n ja raburabu lati bori awon obayeje naa, sugbon nnkan ko tii rogbo.
Bee ni awon loba-loba, nijoye-nijoye ati awon egbe alagbara miiran n se akitiyan.
Ninu iforowanilenuwo kan pelu Baba Suwe, o ni Ikorodu ni won bi oun si, ibe ni oun ti dagba, ibe si ni oun n gbe bayii.
O ni ki a ma paro, ohun ti awon Badooo n se buru jai, to si je pe o ti mu ki opo eniyan ko jade ni ilu.
Bakan naa, Adebayo Salami ati Funsho Adeolu, to je pe Ikorodu ni awon naa n gbe, so pe ohun ti Badoo n fi oju awon eniyan ri buru jai.
Oga Bello ni oun ti foro mo Olorun lokan, nigba ti Adeolu ni oro awon alakatakiti wa kaakiri Naijiria ati orile-ede agbaye.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…