Home ÀKỌ̀TUN Erékéré: Wọ́n ní Evans ti pòórá!. Ṣe egbé ló lò ni àbí àfẹ́ẹ̀rí?
ÀKỌ̀TUN - July 8, 2017

Erékéré: Wọ́n ní Evans ti pòórá!. Ṣe egbé ló lò ni àbí àfẹ́ẹ̀rí?

 

 

Afi ki iroyin kan to n ja rainrain bayii ma je otito. Won ni ogbologbo ajinigbe, Chukwudumeje George Onwuamadike, ti adape re n je Evans, ti salo.

Atimo awon olopaa lo ti wa latigba ti won ti gba a mu ni Magodo ni ilu Eko.

Lasiko ti a n ko iroyin yi jo, iwadii si n lo lowo lori ibi to wa.

Awon olopaa ko tii so gbedeke lori oro yii. Awon kan n so labele pe Evans ku, awon kan ni o ni aisan kansa, nigba ti awon kan so pe won ti taari re lo si Abuja ni.

Bi oro ba ri bee, ibeere ti awon omo Naijiria yoo maa bi Evans ni pe se egbe ni Evans lo ni tabi afeeri?

Egbe ni oogun ti awon baba wa fi maa n poora logan, ti afeeri si je eyi ti won fi maa n ji nnkan mu ti eni kankan ko fi ni foju gan-an-ni won.

Sugbon sa o, awon olopaa ti so pe Evans wa pelu awon. Won ni aheso oro ti ko lese nile ni pe o ti sa danu.

Oka Olopaa amuni-modaa Aba kyari ni egberu Saamu Evans ko le sa mo Olorun lowo.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…