Home iroyin Èmi kò le da ìtàn Ìbàdàn rú – Olúbàdàn
iroyin - July 8, 2017

Èmi kò le da ìtàn Ìbàdàn rú – Olúbàdàn

Se yooba bo won ni Aaro to ba tutu ladie e ye si,be e ni  ko si n ti o bi ori buruku fun enikeni ju yiya olundu.Olubadan ti ileebadan,Alayeluwa Oba Soliu Akanmu Adetunji,ti fesi lati tanmole si oro kan ti o n ja ra-in  ra-in lori igbese Gomina ipinle Oyo Sinato Abiola Ajimobi,lori atunto oye jije nileebadan. Gege bii Iroyin Owuro ti gbo,atunto naa ti o je imosi gomina ni a gbo pe o lowo awon igbimo eleni meje,ti yoo sagbeyewo eto oye naa,ni ero pe,o fe ki awon agbegbe kereje. kereje ti awon baale n dari i won  o lanfaani lati maa dade,dipo ti o fi je Olubadan nikan ,nigba ti awon ilana min- in tun wa labe atunto naa bi i ojo ori,eto ilera,iwe eri onitoun lori eko ati bee bee lo. Ni ifesi si erongba  gomina lori oro naa,awon agba oye kan nile lbadan,gba pe ko si n ti o buru,ki gomina se atunto si n ti o ba daru,debi i pe o fojupo,ti o si n mu yanpon yanrin lowo nigba kuugba ,sugbon kii se bi i eto oye jije nileebadan.Won ni igbese gomina naa da biigba teeyan kan fe mo- on mo fopo moyo,nigba ti onitoun roju tan,to n  fatupa wa airoju kiri. Won ni,osupa laawo,eeyan to ba siju wo oorun,oju u re yoo wami.kii se ojuse gomina ni,lati satunto ilana oye jije nileebadan.Awon kan tile so wi pe igbese naa mu ifura dani.Won ni oro naa da bii ole,to yonda araare lati tunlekun onile se,ti laakaye onile be e ba pe,o ye ki o mo pe n ti o wa leyin ofa ju eje. Awon igun ti o ko fara mo igbese naa gba pe ,bi atunto ba ti e maa waye,ojuse igbimo Olubadan ni ,ti won yoo si gbe siwaju gomina fun bibuwolu.Won sapejuwe awon ipinle  ti o mule ti ile Ibadan,bii Ogun,Osun,Ondo, Eko, pe,ko si eyi ti gomina ilu kankan lewaju atunto fun,sibe,won ni idagbasoke. Ati pe,ajisebi Oyo laari, nijo ti won ti n joba nileebadan,ko figba kan si awuyewuye ri,be e naa si ni awon oye mi-in ti o je mo esin ibile,bii Alagbaa,Oluode, Araba ati bee bee lo,tori gbogbo re lo ni eto to gunmo.Won ko sa i menuba a pe,awon eeyan nla nla n wo ilu lbadan,bi i ilu ti o se mu gangan papa a julo,ti o ba je mo eto oye ji je.Won menuba oro ti Asiwaju Bola tinubu so,nigba ti o wa si ilu Ibadan pe, ilana oye jije nileebadan ti to awokose rere fun gbogbo oloselu pata pata,nitori ona to gunmo ti won gba yan oba .O ni ko ni ijangudu ninu rara,eni ti oba kan ti mo ara re.Bakan naa ni won menuba oro ti Aare Orile yii nigba kan ri,Oloye Olusegun Obasanjo so ni Abeokuta,nigba ti Kabiyesi Alayeluwa Oba Soliu Akanmu kan si pe,eto Olodumare ni yi yan olubadan je,tori ko mu awuye wuye lowo.Bi o tile je pe awon kan si gba pe,erongba gomina naa papo mo tawon eeyan  ilu kan,ti won si ni igbagbo pe yoo mu olaju ati idagbasoke ba ilu lbadan,ko jo pe o nitumo ojo iwaju rere niwoye awon igun to taku wonle pe,n ko fe,o sagba a mo bun- un o.

Bi a ko ba gbagbe ,gomina ipinle Oyo Seneto Abiola Ajimobi ni nnkan bii osu osu kan aabo seyin,lo ti sagbekale omo igbimo ti yoo sagbeyewo atunto ilana oye jije odun 1957, nileebadan,eyi ti adajo feyinti Akintunde Boade lewaju won.Awijare gomina ni pe ofin naa ko ri ori gbe isele asiko yii,fun idagbasoke awujo ti o laju, ti o si lafojusun bi awon awujo orile miiran toti goke agba.Gomina ni ero rere ni oun ni ati pe yoo soro ki omo oniluu o lu  ilu pentuka.

Ni bayii, Olubadan ileebadan Oba Soliu Akanmu Adetunji Aje Ogunguniso kinni, ti fesi tako oro ti awon kan n so kiri pe Oba Alayeluwa naa fara mo atunto ilana oye jije nileebadan.O ni iriri lagba,ilana ji je oye ilu ti ni eto,ni isedale ilu kookan.Kabiyesi ni n to ba daru lo nilo atunto, ki i se n ti ko mawuye wuye lowo.O ni pelu opo ilu lo n wo ilu lbadan bii awokose rere papa a julo lori igbese yiyan oba.O ni,opo ilu ni ko rorun fun lati fi oba mii sori apere, bi oba won ba waja,tori won ko ni oju opo to se e to,eyi ni ori ite oba ni awon ilu be e se ma a n sofo fun igba pipe,ti won yoo si pe kanrin kese nile ejo, nigbeyin gbeyin, eni ti ko leto sipo le bo sori ite, leyi ti ko ye ko ri bee.O kadii oro re pe gbogbo n ti eda ba gboke eepe se pata ni yoo jiyin re,ati pe ni toun o,oun ko lodi si ki idagbasoke wa ninu ilu,sugbon, ko si ninu ipinu ati erongba oun ki a satunto n ti ko daru.Siso iru gbolohun be pe oun fara mo atunto ilana oye jije yato si ilana ti o gbe oun depo Olubadan,da biigba ti won n nu majesin lokele.Bi o tile je pe oye lagba a wo,sibe omo onilu ko nii fe ko tu ati pe,n to o wi lasa wi,a ki wi pe n to o lo wi.A ki i si ke mobi agbegbe ,ko pa tofun re mo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…