Home iroyin Ikú bàbá mi ló s’ọmí dakíkanjú, Ambode rántí àtidìde rẹ̀
iroyin - Orisirisi - July 7, 2017

Ikú bàbá mi ló s’ọmí dakíkanjú, Ambode rántí àtidìde rẹ̀

 

Laipe yii, Gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode, lo anfaani ojo ibi odun kerinle-laadota (54 years) re lati boju weyin wo igbesi aye re.

Gomina naa, eni to ti n se bebe ni Ipinle Eko lati nnkan bii odun meji to ti wa lori aleefa, ranti bi nnkan se ha gadigadi fun oun nigba to wa ni kekere.

Ni pataki, o je ki araye mo pe iku baba oun nigba ti oun si je omo ile iwe fi oun logbologbo, sugbon tori pe oun pinnu lati yege, ati wiwa ti Olorun wa pelu oun, nnkan pada senu rere.

Enu gomina ni oro naa ti dun, e ka a gege bi o se so:

“Odun 1981 ni mo se idanwo Higher School Certificate (HSC), idanwo yii ni o maa n waye leyin iwe mewaa (WAEC). Iru ileewe yii ko fi gbogbo ara wopo bii ti tele mo. Orisii ise meta ni mo se ni igba naa, awon ise naa ni – History, Economics ati Geography. Esi idanwo mi ni o dara sikeji si ti akegbe mi to n je Fidelis Odita to jade ni ile iwe Federal Government Collge to wa ni Warri. Mo ni “A” ni Economics, “B” ni History, ati “B” ni Geography nigba ti Odita ni AAB to je esi idanwo to dara ju ni igba naa. Odita ti di Ojogbon bayii. Universtiy of Lagos ni awa mejeeji lo.

“Ti n ko ba ni paro, ohun ti o so mi di okunrin meedogbon bayii ni iku baba mi. Iku baba yii da bi igba ti omi tan leyin eja mi, o wa tun je ki n tete sokan giri. Baba yii ku ni ose keji ti a pari idanwo. Mama to bi mi ko se ise kankan. Ara ohun to tun so mi di okunrin ni ore baba mi kan ti a jo pade ni igba ti mo wa ni Form 3, mo je omo odun mokanla ni igba naa. Baba yii ni n ko le di onisiro owo rara (accountant). O ni isiro owo ko ki n se nnkan to rorun, eyi naa tun je ipenija gidi fun mi. Mo pinnu lokan mi pe eni to ba ni kin laa se ni a n see han. Mo mokan mi giri, mo si gbaju mo eko mi paapaa gbogbo ohun to ba ti nii se pelu isiro owo.

“Mo jade fasiti ni omo odun mokanlelogun. Mo gboye Master ni igba ti mo pe omo odun metalelogun, ti mo si gboye Chartered Accountant ni omo odun merinlelogun. Lati omo odun mokandinlogun ni mo ti n gbe igbe aye oko ati baba lori ebi mi.

“Loju temi, gbogbo ohun daradara ti eniyan ba n se, ko gbaju moo daradara. Paapaa julo ni igba ti o ba da bi igba ti aye fe pare fun oluwa re, ti omi fe tan leyin eja eni naa. Aabo oro laa so fomoluabi, to ba denu re, ko di odidi.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…