Banky W sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí ìjà Wizkid àti Davido
Ija agba to wa laarin akorin hip hop ti a mo si Wizkid ati Davido si n lo ni rebutu o, debi pea won mejeeji si n tahun sira won.
Awon aseyori kan ti Wizkid tun n ni lenu ojo meta yii lo tun hu ija naa jade.
Leyin pe Wizkid n rowo mu nibi to ti n sere kiri ni oke okun, awon olorin nla-nla lagbaaye naa n se ikira fun un.
Asiko yi ni a gbo pe aburo Davido kan pa owe moo pe yebuyebu lasan ni o n se ni ilu oyinbo.
Wizkid naa wad a oun ati Davido lohun pe aseyori ohun kii se wasa. Koda, o ni apa eni ti ohun (voice) re bad a bii ti konko (frog) ko lee ka a rara.
Opo eniyan gba pe Davido ni Wizkid fi n we opolo ati konko.
Sugbon olorin miiran ti a mo si Banky W ti ki awon mejeeji nilo pe ki won so ewe agbeje mowo.
O ni ohun to ye ki won maa se ni ki won gbaju mo ise won.
Ko daruko eni kankan o, sugbon ninu arojinle kan to gbe si afefe, o ran won leti pe eni to ba n wo ariwo oja kii saaba ri nnkan gidi mu kuro loja.
O ni ibi ti won ba si ti n so oko, ti won so ogulutu, teru-tome lo maa n fara gba a.
O ni ti won ba si n ju okuta sinu erofo, gbogbo eniyan ni yoo fi ara gba idoti.
IROYIN OWURO gbo pe akorin hip hop miiran kan ti oruko re n je Tekno naa wa lara awon to n ja ija agba naa.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…