Home LÁGBO ÀRÍYÁ Àwo orin tuntun THE KING: Ǹjẹ́ D’Banj lè padà sí ipò tó wà tẹ́lẹ̀?
LÁGBO ÀRÍYÁ - July 7, 2017

Àwo orin tuntun THE KING: Ǹjẹ́ D’Banj lè padà sí ipò tó wà tẹ́lẹ̀?

 

Inu akorin hip hop, D’Banj ati awon ololufe re n dun sinkin bayii, tori o ti gbe awo orin tuntun jade.

Akole awo naa ni THE KING, to tumo si OBA ALAYE.

Pelu awo tuntun naa, o di awo orin merin ototo ti D’Banj da se.

Ireti awon ololufe akorin naa ni pe nnkan yoo tubo senu rere fun un pada.

Lati nnkan bii odun mefa seyin ni irawo D’Banj ko ti tan bi o se n tan tele mo. Koda, awon orin to n gbe jade ko lale bo se maa n lale mo. Bee won kop e e si ayeye bi won se maa n pe e tele, nibi to ti maa n so pe, I AM D BANJ!

Wahala to ba a bere nigba ti oun ati olubadasepo re tele, Don Jazzy, ja, ti o si kuro ninu egbe Mo Hits ti won jo da sile, ti won si fi n gbe orin jade.

Bakan naa, irinajo ti D’Banj se lo si ilu oyinbo, to si n lo gbe ibe, se akoba fun un gidi. Ko rowo mu ni ibe. Sugbon nigba ti yoo fi de, awon akorin yoku ti palemo.

Ibeere ti o wa lokan awon eniyan bayii nip e: Nje awo orin THE KING yoo da irawo re pada?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…