Home iroyin Remi Surutu kọ lẹ́tà ìfẹ́ sí ọmọ rẹ̀ tó saláìsí
iroyin - Orisirisi - July 6, 2017

Remi Surutu kọ lẹ́tà ìfẹ́ sí ọmọ rẹ̀ tó saláìsí

 

Oro iya lara omo, nnkan nla ni. Adura gbogbo obi si ni pe ki oniwaju ma keyin, ki eleyin ma siwaju.

Sugbon bi ohun ti eniyan ko fe ba ti sele, o di dandan ki oluware gba fun Olorun oba.

Okan lara awon omo onifiimu Yoruba, Remi Surutu, ti di oloogbe loooto, sugbon obinrin naa si gba pe omo naa ti oruko re n je Ayomikun yoo ma gbohun oun nibi to ba wa.

Idi niyi to fi ko leta ife si omo naa, o ni leyin pe awon jo sepo laye ninu ojo ati ninu ooru, lasiko erin pelu wahala, ife nla kan wa laarin awon ti ko see fenu so.

O ni gege bi iya, kii se adura oun lati ri Ayomikun ko maa je irora, debi pe lawon asiko kan ti irora nla de ba omo naa, o maa n wu oun ki Olorun gbe irora naa si ori oun iya re.

Remi Surutu ni, “Iwo ni aburo mi akoko. Wiwaye re je okan lara awon nnkan to dara julo to sele si mi. Iwo ni alasiri mi. Dupe ati Temilade n saaro re. N ko nigbagbe re laelae. Igbagbo mi ni pe a yoo tun rira nigba to ba ya. Adura mi fun e, ati ife mi si e yoo wa titi ayeraye.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…